Mark 10:23-27

23Jesu wò ó bí ọkùnrin náà ti ń lọ. Ó yípadà, ó sì sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Àní, ohun ìṣòro ni fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run!”

24Ọ̀rọ̀ yìí ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́nu. Jesu tún sọ fún wọn pé, “Ẹyin ọmọ yóò tí ṣòro tó fún àwọn tí ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ọrọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run. 25Ó rọrùn fún ìbákasẹ láti gba ojú abẹ́rẹ́ wọlé jù fún ọlọ́rọ̀ kan láti wọ ìjọba ọ̀run.”

26Ẹnu túbọ̀ ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sí i. Wọ́n béèrè wí pé, “Tí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ta ni nínú ayé ni ó lè ní ìgbàlà?”

27Jesu wò wọ́n, ó sì wí fún wọn pé, “Ènìyàn ní èyí kò ṣe é ṣe fún ṣùgbọ́n kì í ṣe fún Ọlọ́run, nítorí ohun gbogbo ni ṣíṣe fún Ọlọ́run.”

Copyright information for YorBMYO